2 Samuel 10:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ọba wí pé, “N óo ṣe ẹ̀tọ́ fún Hanuni, ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe ẹ̀tọ́ fún mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti tù ú ninu, nítorí ikú baba rẹ̀. Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Dafidi dé Amoni,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi gẹgẹ bi baba rẹ̀ si ti ṣe ore fun mi. Dafidi si ranṣẹ lati tù u ninu lati ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀ wá, nitori ti baba rẹ̀. Awọn iranṣẹ Dafidi si wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí pé, “Èmi yóò ṣe ooré fún Hánúnì ọmọ Náhásì gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ sì ti ṣe oore fún mi.” Dáfídì sì ìránṣẹ́ láti tù ú nínú láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá, nítorí ti baba rẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì wá sí ilé àwọn ọmọ Ámónì.