2 Samuel 10:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àwọn àgbààgbà ìlú náà wí fún Hanuni ọba wọn pé, “Ṣé o rò pé baba rẹ ni Dafidi bu ọlá fún tóbẹ́ẹ̀, tí ó fi rán àwọn oníṣẹ́ láti wá tù ọ́ ninu? Rárá o! Amí ni ó rán wọn wá ṣe, kí wọ́n lè wo gbogbo ìlú wò, kí ó baà lè ṣẹgun wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn olori awọn ọmọ Ammoni si wi fun Hanuni oluwa wọn pe, Li oju rẹ, ọlá ni Dafidi mbù fun baba rẹ, ti o fi ran awọn olutùnú si ọ? ko ha se pe, Dafidi ran awọn iranṣẹ rẹ̀ si ọ, lati wa wò ilu, ati lati ṣe alami rẹ̀, ati lati bà a jẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn olórí àwọn ọmọ Ámónì sì wí fún Hánúnì OLÚWA wọn pé, “Ǹjẹ́ o rò pé Dáfídì ń bu ọlá fún baba rẹ nígbà tí ó rán ènìyàn wá láti bá ọ kẹ́dùn? Kò ha ṣe pé Dáfídì rán àwọn ìránṣẹ́ sí ọ láti wo ìlú àti láti yọ́ ọ wò àti láti gbà ọ́.”