2 Samuel 10:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìtìjú bá wọn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró ní Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, kí wọ́n tó máa pada bọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si sọ fun Dafidi, o si ranṣẹ lọ ipade wọn, nitoriti oju tì awọn ọkunrin na pupọ̀: ọba si wipe. Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọ̀n nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ padà bọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì sọ fún Dáfídì, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jẹ́ríkò títí irungbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”