2 Samuel 10:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ti di ọ̀tá Dafidi, wọ́n ranṣẹ lọ fi owó gba ọ̀kẹ́ kan (20,000) jagunjagun ninu àwọn ará Siria tí wọ́n ń gbé Betirehobu ati Soba. Wọ́n gba ẹgbẹrun (1,000) lọ́dọ̀ ọba Maaka ati ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ará Tobu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Ammoni si ri pe, nwọn di ẹni irira niwaju Dafidi, awọn ọmọ Ammoni si ranṣẹ, nwọn si fi owo bẹ̀ ogun awọn ara Siria ti Betrehobu; ati Siria ti Soba, ẹgbãwa ẹlẹsẹ ati ti ọba Maaka, ẹgbẹrun ọkunrin, ati ti Iṣtobu ẹgbãfa ọkunrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ámónì sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dáfídì, àwọn ọmọ Ámónì sì ránṣẹ, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Síríà ti Bẹtire-hóhù; àti Síríà ti Sóbà, ẹgbaàwá ẹlẹ́sẹ̀ àti ti ọba Máákà, ẹgbẹ̀run ọkùnrin àti ti Isítóbù ẹgbàafà ọkùnrin lọ́wẹ̀.