2 Samuel 10:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Amoni jáde sí àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n tò sí ẹnubodè wọn ní Raba, tíí ṣe olú ìlú wọn. Gbogbo àwọn ọmọ ogun, ará Siria tí wọ́n wá láti Soba ati Rehobu, ati àwọn ará Tobu ati ti Maaka, àwọn dá dúró ninu pápá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Ammoni si jade, nwọn si tẹ́ ogun li ẹnu odi; ara Siria ti Soba, ati ti Rehobu, ati Iṣtobu, ati Maaka, nwọn si tẹ́ ogun ni papa fun ara wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ámónì sì jáde, wọ́n sì tẹ́ ogún ní ẹnu odi; ará Síríà ti Sóbà, àti ti Réhóbù, àti Ísítóbù, àti Máákà, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn.