2 Samuel 11:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò ìgbà tí igi ń rúwé, tí ó jẹ́ àkókò tí gbogbo àwọn ọba máa ń lọ sójú ogun, Dafidi rán Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Israẹli jáde. Wọ́n ṣẹgun àwọn ará Amoni, wọ́n sì dó ti ìlú Raba, ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, lẹhin igbati ọdun yipo, li akoko igbati awọn ọba ima jade ogun, Dafidi si rán Joabu, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati gbogbo Israeli; nwọn si pa awọn ọmọ Ammoni, nwọn si dó ti Rabba. Dafidi si joko ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí ọdún yípo, ní àkókò ìgbà tí àwọn ọba náà ń jáde ogun, Dáfídì sì rán Jóábù, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti gbogbo Ísírẹ́lì; wọ́n sì pa àwọn ọmọ Ámónì, wọ́n sì dó ti Rábà. Dáfídì sì jókòó ní Jérúsálẹ́mù.