2 Samuel 11:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi pè é kí ó wá bá òun jẹ oúnjẹ alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì fún un ní ọtí mu yó, ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí aṣọ òtútù rẹ̀ ni ó sùn, pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ninu ilé ìṣọ́ ọba, ní ààfin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si pè e, o si jẹ, o si mu niwaju rẹ̀; o si mu ki ọti ki o pa a: on si jade li alẹ lọ si ibusùn rẹ̀ lọdọ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì pè é, ó sì jẹ, ó sì mú nítorí rẹ̀; ó sì mu kí ọtí pa á; òun sì jáde ní alẹ́ lọ sí ibùsùn rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ̀, kò sì sọ̀kalẹ́ lọ sí ilé rẹ̀.