2 Samuel 11:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ ti gbàgbé bí wọ́n ti ṣe pa Abimeleki ọmọ Gideoni? Ṣebí obinrin kan ni ó ju ọlọ ata sílẹ̀ láti orí ògiri ní Tebesi, tí ó sì pa á. Kí ló dé tí ẹ fi súnmọ́ ògiri tóbẹ́ẹ̀?’ Bí ọba bá bèèrè irú ìbéèrè yìí, sọ fún un pé, ‘Wọ́n ti pa Uraya, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pẹlu.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tali o pa Abimeleki ọmọ Jerubbeṣeti? Ki iṣe obinrin li o yi okuta ọlọ lù u lati ori odi wá, ti o si kú ni Tebeṣi? ẽha ti ri ti ẹnyin fi sunmọ odi na? Iwọ o si wi fun u pe, Uria iranṣẹ rẹ ará Hitti kú pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni ó pa Ábímélékì ọmọ Jerubu-Bésétì? Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tébésì? Èé ha ti rí tí ẹ̀yín fi súnmọ́ odi náà? Ìwọ yóò sì wí fún-un pé, Ùráyà ìránṣẹ́ rẹ ará Hítì kú pẹ̀lú.’ ”