2 Samuel 11:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Àwọn ọ̀tá wa lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde láti inú ìlú wọn láti bá wa jà ninu pápá, ṣugbọn a lé wọn pada títí dé ẹnubodè ìlú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iranṣẹ na si wi fun Dafidi pe, Nitõtọ awọn ọkunrin na lagbara jù wa lọ, nwọn si jade tọ̀ wa wá ni pápa, awa si tẹle wọn titi nwọn fi de ẹhìn odi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìránṣẹ́ náà sì wí fún Dáfídì pé, “Nítòótọ́ àwọn ọkùnrin náà lágbára jù wá lọ, wọ́n sì jáde tọ̀ wá wá ní pápá, àwa sì tẹ̀lé wọn títí wọ́n fi dé ẹ̀yìn odi.