2 Samuel 11:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi rán oníṣẹ́ náà sí Joabu pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí da ọkàn rẹ rú níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ẹnikẹ́ni kò lè mọ ẹni tí ogun yóo pa. Tún ara mú gidigidi, kí o sì gba ìlú náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun iranṣẹ na pe, Bayi ni iwọ o wi fun Joabu pe, Máṣe jẹ ki nkan yi ki o buru li oju rẹ, nitoripe idà a ma jẹ li ọtun li òsi, mu ijà rẹ le si ilu na, ki o si bì i ṣubu: ki iwọ ki o si mu u lọkàn le.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún ìránṣẹ́ náà pé, “Báyìí ni ìwọ yóò wí fún Jóábù pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí nǹkan yìí burú ní ojú rẹ, nítorí pé idà a máa jẹ́ lọ́tún lósì, mú ìjà rẹ le sí ìlú náà, kí o sì bì í ṣubú.’ Kí ìwọ sì mú un lọ́kàn le.”