2 Samuel 11:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àkókò ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Dafidi ní kí wọ́n mú un wá sí ààfin, Batiṣeba sì di aya rẹ̀. Ó bí ọmọkunrin kan fún un, ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí ohun tí Dafidi ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awẹ̀ na si kọja tan, Dafidi si ranṣẹ, o si mu u wá si ile rẹ̀, on si wa di aya rẹ̀, o si bi ọmọkunrin kan fun u. Ṣugbọn nkan na ti Dafidi ṣe buru niwaju Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ìṣọ̀fọ̀ náà sì kọjá tan, Dáfídì sì ránṣẹ́, o sì mú un wá sí ilé rẹ̀, ó sì di aya rẹ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un, ṣùgbọ́n nǹkan náà tí Dáfídì ṣe burú níwájú OLÚWA.