2 Samuel 12:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà kú, ẹ̀rù sì ba àwọn iranṣẹ Dafidi láti sọ fún un pé ọmọ ti kú. Wọ́n ní, “Ìgbà tí ọmọ yìí wà láàyè, a bá Dafidi sọ̀rọ̀, kò dá wa lóhùn. Báwo ni a ṣe fẹ́ sọ fún un pé ọmọ ti kú? Ó lè pa ara rẹ̀ lára.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ni ijọ keje, ọmọ na si kú. Awọn iranṣẹ Dafidi si bẹ̀ru lati wi fun u pe, ọmọ na kú: nitori ti nwọn wipe, Kiye si i, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, awa sọ̀rọ fun u, on kò si gbọ́ ohùn wa: njẹ yio ti ṣẹ́ ara rẹ̀ ni iṣẹ́ to, bi awa ba wi fun u pe, ọmọ na kú?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ijọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsí i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní ìṣẹ́ tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”