2 Samuel 12:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Dafidi rí i pé wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ó fura pé ọmọ ti kú. Ó bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ọmọ ti kú ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ó ti kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Dafidi si ri pe awọn iranṣẹ rẹ̀ nsọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ, Dafidi si kiye si i pe ọmọ na kú: Dafidi si bere lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ọmọ na kú bi? nwọn si da a li ohùn pe, O kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Dáfídì sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dáfídì sì kìyésí i, pé ọmọ náà kú: Dáfídì sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.”