2 Samuel 12:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bi í pé, “Kabiyesi, ọ̀rọ̀ yìí rú wa lójú, kí ni ohun tí ò ń ṣe yìí? Nígbà tí ọmọ yìí wà láàyè, ò ń gbààwẹ̀, ò ń sọkún nítorí rẹ̀. Ṣugbọn gbàrà tí ó kú tán, o dìde o sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹun!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iranṣẹ rẹ̀ si bi li ere pe, Ki li eyi ti iwọ ṣe yi? nitori ọmọ na nigbati o mbẹ lãye iwọ gbawẹ, o si sọkun; ṣugbọn nigbati ọmọ na kú, o dide o si jẹun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí lèyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láàyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sunkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”