2 Samuel 12:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi dá wọn lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí ó wà láàyè, mo gbààwẹ̀, mo sì sọkún, pé bóyá OLUWA yóo ṣàánú mi, kí ó má kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, nigbati ọmọ na mbẹ lãye, emi gbawẹ, emi si sọkun: nitoriti emi wipe, Tali o mọ̀ bi Ọlọrun o ṣãnu mi, ki ọmọ na ki o le yè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sunkún: nítorí tí Èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’