2 Samuel 12:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti kú, kí ni n óo tún máa gbààwẹ̀ sí? Ṣé mo lè jí i dìde ni? Èmi ni n óo tọ̀ ọ́ lọ, kò tún lè pada tọ̀ mí wá mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nisisiyi o ti kú, nitori kili emi o ṣe ma gbawẹ? emi le mu u pada wá mọ bi? emi ni yio tọ̀ ọ lọ, on ki yio si tun tọ̀ mi wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú-un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”