2 Samuel 12:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn ọkunrin talaka yìí kò ní nǹkankan, àfi ọmọ aguntan kékeré kan tí ó rà, tí ó sì ń tọ́jú títí tí ó fi dàgbà ninu ilé rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ninu oúnjẹ tí òun pàápàá ń jẹ ni ó ti ń fún un jẹ, igbá tí ọkunrin yìí fi ń mu omi ni ó fi ń bu omi fún ọmọ aguntan rẹ̀ mu. A sì máa gbé e jókòó lórí ẹsẹ̀, bí ẹni pé ọmọ rẹ̀ gan-an ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọkunrin talaka na kò si ni nkan, bikoṣe agutan kekere kan, eyi ti o ti rà ti o si ntọ́: o si dagba li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ rẹ̀; a ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀, a si ma mu ninu ago rẹ̀, a si ma dubulẹ li aiya rẹ̀, o si dabi ọmọbinrin kan fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọkùnrin talákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́: ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀; a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dúbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un.