2 Samuel 12:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ṣí adé wúrà orí ọba wọn, adé náà wọ̀n tó ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, ó sì ní òkúta olówó iyebíye kan lára, ó sì fi dé orí ara rẹ̀. Dafidi kó ọpọlọpọ àwọn ìkógun mìíràn ninu ìlú náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si gba adé ọba wọn kuro li ori rẹ̀, wuwo rẹ̀ si jẹ talenti wura kan, o si ni okuta oniyebiye lara rẹ̀: a si fi i de Dafidi li ori. On si kó ikogun ilu na li ọ̀pọlọpọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ talẹ́ńtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀; a sì fi dé Dáfídì lórí. Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀.