2 Samuel 12:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo àwọn ará ìlú náà ṣiṣẹ́. Àwọn kan ń lo ayùn, àwọn mìíràn ń lo ọkọ́ onírin, ati àáké onírin, àwọn mìíràn sì ń gé bulọọku, wọ́n ń sun ún. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sí àwọn ará ìlú Amoni yòókù. Lẹ́yìn náà, òun ati àwọn eniyan rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si kó awọn enia na ti o wà ninu rẹ̀, o si fi wọn si iṣẹ ayùn, ati si iṣẹ nkan iwọlẹ ti a fi irin ṣe, ati si iṣẹ ãke irin, o si fi wọn si iṣẹ biriki mímọ: bẹ̃na li on si ṣe si gbogbo ilu awọn ọmọ Ammoni. Dafidi ati gbogbo awọn enia na si pada si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtùlẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe: bẹ́ ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ámónì. Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jérúsálẹ́mù.