2 Samuel 12:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, àlejò dé bá ọkunrin olówó ninu ilé rẹ̀. Ọkunrin yìí kò fẹ́ fọwọ́ kan èyíkéyìí ninu ẹran tirẹ̀ láti pa ṣe àlejò náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹyọ ọmọ aguntan kan tí talaka yìí ní, ni olówó yìí gbà, tí ó sì pa ṣe àlejò.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alejo kan si tọ̀ ọkunrin ọlọrọ̀ na wá, on kò si fẹ mu ninu agutàn rẹ̀, ati ninu malu rẹ̀, lati fi ṣe alejo fun ẹni ti o tọ̀ ọ wá: o si mu agutan ọkunrin talaka na fi ṣe alejo fun ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àlejò kan sì tọ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wá, òun kò sì fẹ́ mú nínú àgùntàn rẹ̀, àti nínú màlúù rẹ̀: láti fi ṣe àlejò fún ẹni tí ó tọ̀ ọ́ wá: o sì mú àgùntàn ọkùnrin talákà náà fi ṣe àlejò fún ọkùnrin tí ó tọ̀ ọ́ wá.”