2 Samuel 12:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Dafidi gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú bí i gidigidi sí ọkunrin ọlọ́rọ̀ náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi OLUWA Alààyè búra pé ẹni tí ó dán irú rẹ̀ wò, kíkú ni yóo kú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibinu Dafidi si fàru gidigidi si ọkunrin na; o si wi fun Natani pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkunrin na ti o ṣe nkan yi, kikú ni yio kú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìbínú Dáfídì sì fàru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Nátanì pé, “Bí OLÚWA ti ń bẹ láàyè: ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkán yìí, kíkú ni yóò kú.