2 Samuel 12:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ló dé tí o fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, tí o sì ṣe nǹkan burúkú yìí níwájú rẹ̀. Ìwọ ni o fi Uraya fún ogun pa; tí o jẹ́ kí àwọn Amoni pa á. Lẹ́yìn náà, o gba aya rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eṣe ti iwọ fi kẹgàn ọ̀rọ Oluwa, ti iwọ fi ṣe nkan ti o buru li oju rẹ̀, ani ti iwọ fi fi idà pa Uria ará Hitti, ati ti iwọ fi mu obinrin rẹ̀ lati fi ṣe obinrin rẹ, o si fi idà awọn ọmọ Ammoni pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gan ọ̀rọ̀ OLÚWA, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Ùráyà ará Hítì, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.