2 Samuel 13:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Iranṣẹ náà bá ti Tamari jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. Aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ alápá gígùn, irú èyí tí àwọn ọmọ ọba, obinrin, tí kò tíì wọlé ọkọ máa ń wọ̀, ni Tamari wọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si ni aṣọ alaràbara kan li ara rẹ̀: nitori iru aṣọ awọ̀leke bẹ̃ li awọn ọmọbinrin ọba ti iṣe wundia ima wọ̀. Iranṣẹ rẹ̀ si mu u jade, o si ti ilẹkun mọ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan làra rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúndíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ ọn.