2 Samuel 13:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Absalomu, ẹ̀gbọ́n Tamari, rí i, ó bi í léèrè pé, “Ṣé Amnoni bá ọ lòpọ̀ ni? Jọ̀wọ́, arabinrin mi, gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ọmọ baba kan náà ni ẹ̀yin mejeeji, nítorí náà, má sọ fún ẹnikẹ́ni.” Tamari bá ń gbé ilé Absalomu. Òun nìkan ni ó dá wà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ pupọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀ si bi i lere pe, Amnoni ẹgbọ́n rẹ ba ọ ṣe bi? njẹ aburo mi, dakẹ; ẹgbọ́n rẹ ni iṣe; má fi nkan yi si ọkàn rẹ. Tamari si joko ni ibanujẹ ni ile Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Ámúnónì ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Támárì sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Ábúsálómù ẹ̀gbọ́n rẹ̀.