2 Samuel 13:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba ní, “Rárá, ọmọ mi, bí gbogbo wa bá lọ, wahala náà yóo pọ̀jù fún ọ.” Absalomu rọ ọba títí, ṣugbọn ó kọ̀ jálẹ̀. Ọba bá súre fún un, ó ní kí ó máa lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun Absalomu pe, Bẹ̃kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, má jẹ ki gbogbo wa lọ, ki a má mu ọ nawo pupọ. O si rọ̀ ọ gidigidi, ṣugbọn on kò fẹ lọ, o si sure fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí fún Ábúsálómù pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má báà mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.