2 Samuel 13:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn iranṣẹ náà bá tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀, wọ́n sì pa Amnoni. Gbogbo àwọn ọmọ Dafidi yòókù bá gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì sá lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iranṣẹ Absalomu si ṣe si Amnoni gẹgẹ bi Absalomu ti paṣẹ. Gbogbo awọn ọmọ ọba si dide, olukuluku gun ibaka rẹ̀, nwọn si sa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìránṣẹ́ Ábúsálómù sì ṣe sí Ámúnónì gẹ́gẹ́ bí Ábúsálómù ti páṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlukú gun ìbaka rẹ̀, wọ́n sì sá.