2 Samuel 13:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Jonadabu, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi, wí fún ọba pé, “Kabiyesi, ẹnikẹ́ni kò pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ. Amnoni nìkan ni Absalomu pàṣẹ pé kí wọ́n pa. Láti ìgbà tí Amnoni ti fi ipá bá Tamari, arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, ni ó ti pinnu láti ṣe ohun tí ó ṣe yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jonadabu ọmọ Ṣimea arakonrin Dafidi si dahùn o si wipe, Ki oluwa mi ọba ki o máṣe rò pe nwọn ti pa gbogbo awọn ọdọmọde-kọnrin awọn ọmọ ọba; nitoripe Amnoni nikanṣoṣo li o kú: nitori lati ẹnu Absalomu wá li a ti pinnu rẹ̀ lati ọjọ ti o ti fi agbara mu Tamari aburo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jónádábù ọmọ Ṣíméà arakùnrin Dáfídì sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí OLÚWA mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdé-kùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Ámúnónì nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Ábúsálómù wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Támárì àbúrò rẹ̀.