2 Samuel 13:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Absalomu sá lọ ní àkókò yìí. Kò pẹ́ rárá, lẹ́yìn náà, ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ̀nà tí ó wọ ìlú rí ogunlọ́gọ̀ eniyan, wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀nà Horonaimu, lẹ́bàá òkè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Absalomu si sa. Ọdọmọkunrin na ti nṣọ̀na si gbe oju rẹ̀ soke, o si ri pe, ọ̀pọ enia mbọ̀ li ọ̀na lẹhin rẹ̀ lati iha oko wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúsálómù sì sá. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si ríi pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ̀nà lẹ́yin rẹ̀ láti ìhà òkè wá.”