2 Samuel 13:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó fẹ́rẹ̀ má tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, tí àwọn ọmọ Dafidi fi wọlé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, Dafidi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ náà sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati o ti pari ọ̀rọ isọ, si wõ, awọn ọmọ ọba de, nwọn si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun: ọba ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu si sọkun nlanla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sòkè, wọ́n sì sunkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá.