2 Samuel 14:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Obinrin yìí tún wí fún ọba pé, “Kabiyesi, jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ kí ẹni tí ó fẹ́ gbẹ̀san ikú ọmọ mi kinni má baà pa ọmọ mi keji.” Dafidi ọba bá dáhùn pé, “Mo ṣèlérí fún ọ, ní orúkọ OLUWA Ọlọrun alààyè, pé, ẹnikẹ́ni kò ní ṣe ọmọ rẹ ní ohunkohun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba ki o ranti Oluwa Ọlọrun rẹ̀, ki olugbẹsan ẹjẹ ki o máṣe ni ipa lati ṣe iparun, ki nwọn ki o má bà pa ọmọ mi; on si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkan ninu irun ori ọmọ rẹ ki yio bọ́ silẹ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí ọba ó rántí OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má ṣe ní ipá láti ṣe iparun, kí wọn o má bá a pa ọmọ mi!” Òun sì wí pé, “Bí OLÚWA ti ń bẹ láàyè ọ̀kan nínú irun orí ọmọ rẹ ki yóò bọ sílẹ̀.”