2 Samuel 14:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Obinrin náà wí pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe ohun tí ó burú yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun? Ọ̀rọ̀ tí o sọ tán nisinsinyii, ara rẹ gan-an ni o fi dá lẹ́bi, nítorí pé, o kò jẹ́ kí ọmọ rẹ pada wá sílé láti ibi tí ó sá lọ?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Obinrin na si wipe, Nitori kini iwọ si ṣe ro iru nkan yi si awọn enia Ọlọrun? nitoripe ọba si sọ nkan yi bi ẹniti o jẹbi, nitipe ọba kò mu isánsa rẹ̀ bọ̀ wá ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Obìnrin náà sì wí pé, “Nítorí kínni ìwọ sì ṣe ro irú nǹkan yìí sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run? Nítorí pé ní sísọ nǹkan yìí ọba ní ẹ̀bi, nítorí pé ọba kò mú ìsáǹsá rẹ̀ bọ̀ wá ilé.