2 Samuel 14:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kabiyesi, ìdí tí mo fi kó ọ̀rọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá ni pé, àwọn eniyan ń dẹ́rùbà mí, èyí ni ó mú kí n rò ninu ara mi pé, n óo wá bá ọ sọ̀rọ̀, mo sì ní ìrètí pé, kabiyesi yóo ṣe ohun tí mo wá bẹ̀bẹ̀ pé kí ó bá mi ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina li emi si ṣe wá isọ nkan yi fun oluwa mi ọba, bi o jẹpe awọn enia ti dẹrubà mi; iranṣẹbinrin rẹ si wi pe, Njẹ emi o sọ fun ọba; o le ri bẹ̃ pe ọba yio ṣe ifẹ iranṣẹbinrin rẹ̀ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ nítorí náà ni èmi sì ṣe wá sọ nǹkan yìí fún OLÚWA mi ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ti dẹ́rùbà mí; ìránṣẹ́bìnrin rẹ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ èmi ó sọ fún ọba; ó lè rí bẹ́ẹ̀ pé ọba yóò ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún un.