2 Samuel 14:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba bá bí i pé, “Ṣé Joabu ni ó rán ọ ní gbogbo iṣẹ́ tí o wá jẹ́ yìí, àbí òun kọ?” Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bí o ti bèèrè ìbéèrè yìí kò jẹ́ kí n mọ̀ bí mo ti lè yí ẹnu pada rárá. Òtítọ́ ni, Joabu ni ó kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo sọ, ati gbogbo bí mo ti ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wipe, Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹlu rẹ ninu gbogbo eyi? obinrin na si dahun o si wipe, Bi ẹmi rẹ ti mbẹ lãye, oluwa mi ọba, kò si iyipada si ọwọ́ ọtun, tabi si ọwọ́ osi ninu gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti wi: nitoripe Joabu iranṣẹ rẹ, on li o rán mi, on li o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi si iranṣẹbinrin rẹ li ẹnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Jóábù kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?” Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láàyè, OLÚWA mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí OLÚWA mi ọba ti wí: nítorí pé Jóábù ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu.