2 Samuel 14:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ó ranṣẹ sí ọlọ́gbọ́n obinrin kan, tí ń gbé Tekoa. Nígbà tí obinrin yìí dé, Joabu wí fún un pé, “Ṣe bí ẹni pé o wà ninu ọ̀fọ̀, wọ aṣọ ọ̀fọ̀, má fi òróró para, kí o sì fi irun rẹ sílẹ̀ játijàti. Ṣe bí ẹni tí ó ti wà ninu ọ̀fọ̀ fún ọjọ́ pípẹ́;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joabu si ranṣẹ si Tekoa, o si mu ọlọgbọn obinrin kan lati ibẹ̀ wá, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, ṣe bi ẹniti nṣọfọ, ki o si fi aṣọ ọfọ sara, ki o má si ṣe fi ororo pa ara, ki o si dabi obinrin ti o ti nṣọ̀fọ fun okú li ọjọ pupọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóábù sì ránṣẹ́ sí Tekóà, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀.