2 Samuel 14:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni ọba sọ fún Joabu pé, “Mo ti pinnu láti ṣe ohun tí o fẹ́ kí n ṣe. Lọ, kí o sì mú Absalomu, ọmọ mi, pada wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun Joabu pe, Wõ, emi o ṣe nkan yi: nitorina lọ, ki o si mu ọmọdekunrin na Absalomu pada wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí fún Jóábù pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí: nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Ábúsálómù padà wá.”