2 Samuel 14:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ọba pàṣẹ pé kí Absalomu máa gbé ilé rẹ̀, nítorí pé òun kò fẹ́ rí i sójú. Nítorí náà, inú ilé Absalomu ni ó ń gbé, kò sì dé ọ̀dọ̀ ọba rárá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wipe, Jẹ ki o yipada lọ si ile rẹ̀, má si ṣe jẹ ki o ri oju mi. Absalomu si yipada si ile rẹ̀, kò si ri oju ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Ábúsálómù sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba.