2 Samuel 14:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni í máa ń gé irun orí rẹ̀, nígbà tí ó bá kún, tí ó sì gùn ju bí ó ti yẹ lọ. Tí wọ́n bá fi ìwọ̀n ọba wọn èyí tí wọ́n bá gé lára irun rẹ̀, a máa tó igba ṣekeli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o ba si rẹ́ irun ori rẹ̀ (nitoripe li ọdọdun li on ima rẹ́ ẹ nitoriti o wuwo fun u, on a si ma rẹ́ ẹ) on si wọ̀n irun ori rẹ̀, o si jasi igba ṣekeli ninu òṣuwọn ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó bá sì rẹ́ irun orí rẹ̀ (nítorí pé lọ́dọ̀ọdún ni òun máa ń rẹ́ ẹ. Nígbà tí ó bá wúwo fún un, òun a sì máa rẹ́ ẹ) òun sì wọn irun orí rẹ̀, ó sì jásí igba ṣẹ́kẹ́lì nínú òṣùwọ̀n ọba.