2 Samuel 14:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Absalomu dáhùn pé, “Nítorí pé mo ranṣẹ pè ọ́, pé kí o wá, kí n lè rán ọ lọ bèèrè lọ́wọ́ ọba pé, ‘Kí ni mo kúrò ní Geṣuri tí mo sì wá síhìn-ín fún? Ìbá sàn kí n kúkú wà lọ́hùn-ún.’ Mo fẹ́ kí o ṣe ètò kí n lè fi ojú kan ọba, bí ó bá sì jẹ́ pé mo jẹ̀bi, kí ó pa mí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Absalomu si da Joabu lohùn pe, Wõ, emi ranṣẹ si ọ, wipe, Wá nihinyi, emi o si rán ọ lọ sọdọ ọba, lati wi pe, Kili emi ti Geṣuri wá si? iba sàn fun mi bi o ṣepe emi wà nibẹ̀ sibẹ. Njẹ emi nfẹ ri oju ọba; bi o ba si ṣe pe ẹ̀ṣẹ mbẹ li ara mi, ki o pa mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúsálómù sì dá Jóábù lóhùn pé, “Wò ó, èmi ránṣẹ́ sí ọ, wí pé, ‘Wá níhìn-ín yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sọ́dọ̀ ọba, láti béèrè pé, “Kí ni èmi ti Géṣúrì wá si? Ìbá sàn fún mí bí ó ṣe pé èmi wà lọ́hùn-ún ṣíbẹ̀!” ’ Ǹjẹ́ nísinsin yìí jẹ́ kí èmi lọ síwájú ọba bí ó bá sì ṣe ẹ̀bi ń bẹ nínú mi, kí ó pa mí.”