2 Samuel 14:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọmọkunrin meji ni mo bí. Ní ọjọ́ kan, àwọn mejeeji ń bá ara wọn jà ninu pápá, kò sì sí ẹnikẹ́ni nítòsí láti là wọ́n, ni ọ̀kan ninu wọn bá lu ekeji rẹ̀ pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iranṣẹbinrin rẹ si ti li ọmọkunrin meji, awọn mejeji si jọ jà li oko, kò si si ẹniti yio là wọn, ekini si lu ekeji, o si pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ sì ti ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì sì jọ jà lóko, kò sì si ẹni tí yóò là wọ́n, èkínní sì lu èkejì, ó sì pa á.