2 Samuel 14:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii, kabiyesi, gbogbo àwọn eniyan mi ni wọ́n ti kẹ̀yìn sí mi. Wọ́n ní dandan kí ń fa ọmọ mi kan yòókù kalẹ̀ fún àwọn, kí wọ́n lè pa á nítorí arakunrin rẹ̀ tí ó pa. Bí mo bá gbà fún wọn, kò ní sí ẹni tí yóo jogún ọkọ mi, wọn yóo já ìrètí mi kan tí ó kù kulẹ̀, kò sì ní sí ọmọkunrin tí yóo gbé orúkọ ọkọ mi ró, tí orúkọ náà kò fi ní parun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wõ, gbogbo idile dide si iranṣẹbinrin rẹ, nwọn si wipe, Fi ẹni ti o pa ẹnikeji rẹ̀ fun wa, awa o si pa a ni ipo ẹmi ẹnikeji rẹ̀ ti o pa, awa o si pa arole na run pẹlu: nwọn o si pa iná mi ti o kù, nwọn kì yio si fi orukọ tabi ẹni ti o kù silẹ fun ọkọ mi li aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì wò ó, gbogbo ìdílé dìde sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, wọ́n sì wí pé, Fi ẹni tí ó pa arákùnrin rẹ fún wa, àwa ó sì pa á ní ipò ẹ̀mi arákùnrin rẹ̀ tí ó pa, àwa ó sì pa àrólé náà run pẹ̀lú: wọn ó sì pa iná mi tí ó kù, wọn kì yóò sì fi orúkọ tàbí ẹni tí ó kú silẹ̀ fún ọkọ mi ní ayé.”