2 Samuel 14:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Obinrin náà wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbogbo ohun tí o bá ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí, èmi ati ìdílé mi ni a ni ẹ̀bi rẹ̀, ẹ̀bi rẹ̀ kò kan kabiyesi ati ìdílé rẹ̀ rárá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Obinrin ara Tekoa na si wi fun ọba pe, Oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀ṣẹ na ki o wà lori mi, ati lori idile baba mi; ki ọba ati itẹ rẹ̀ ki o jẹ́ alailẹbi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Obìnrin ará Tékóà náà sì wí fún ọba pé, “OLÚWA mi, ọba, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lórí mi, àti lorí idilé baba mí; kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ aláìlẹ́bi.”