2 Samuel 15:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Absalomu ń rúbọ lọ́wọ́, ó ranṣẹ sí ìlú Gilo láti lọ pe Ahitofeli ará Gilo, ọ̀kan ninu àwọn olùdámọ̀ràn Dafidi ọba. Ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì ń gbilẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà ń pọ̀ sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Absalomu si ranṣẹ pè Ahitofeli ara Giloni, igbimọ̀ Dafidi, lati ilu rẹ̀ wá, ani lati Gilo, nigbati o nrú ẹbọ. Idìtẹ̀ na si le; awọn enia si npọ̀ sọdọ Absalomu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábúsálómù sì ránṣẹ́ pe Áhítófélì ará Gílónì, ìgbìmọ̀ Dáfídì, láti ìlú rẹ̀ wá, àní láti Gílónì, nígbà tí ó ń rú ẹbọ. Ìdìmọ̀lù náà sì le; àwọn ènìyàn sì ń pọ̀ sọ́dọ̀ Ábúsálómù.