2 Samuel 15:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Jerusalẹmu pé, “A gbọdọ̀ sá lọ lẹsẹkẹsẹ, bí a kò bá fẹ́ bọ́ sọ́wọ́ Absalomu. Ẹ ṣe gírí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo bá wa, yóo ṣẹgun wa, yóo sì pa ìlú yìí run.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ ni Jerusalemu pe, Ẹ dide, ẹ jẹ ki a salọ, nitoripe kò si ẹniti yio gbà wa lọwọ Absalomu: ẹ yara, ki a lọ kuro, ki on má ba yara le wa ba, ki o má si mu ibi ba wa, ki o má si fi oju idà pa ilu run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sá lọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Ábúsálómù; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má báà yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.”