2 Samuel 15:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò sì tíì pẹ́ pupọ tí o dé, kí ló dé tí o fi fẹ́ máa bá mi káàkiri ninu ìrìnkèrindò mi? Èmi gan-an nìyí, n kò tíì mọ ibi tí mò ń lọ. Pada kí àwọn ará ìlú rẹ gbogbo sì máa bá ọ lọ. OLUWA yóo fẹ́ràn ìwọ náà, yóo sì dúró tì ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lana yi ni iwọ de, emi ha si le mu ki iwọ ma ba wa lọ kakiri loni bi? emi nlọ si ibikibi ti mo ba ri: pada, ki o si mu awọn arakunrin rẹ pada, ki ãnu ati otitọ ki o pẹlu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lánàá yìí ni ìwọ dé, èmi ó ha sì mú kí ìwọ máa bá wá lọ kákiri lónìí bí? Èmi ń lọ sí ibikíbi tí mo bá rí: padà, kí o sì mú àwọn arakùnrin rẹ padà, kí àánú àti òtítọ́ OLÚWA wà pẹ̀lú rẹ.”