2 Samuel 15:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Itai dáhùn pé, “Kabiyesi, mo fi OLUWA búra, bí ẹ̀mí oluwa mi ọba tí ń bẹ láàyè, pé, ibikíbi tí o bá ń lọ ni n óo máa bá ọ lọ, kì báà tilẹ̀ já sí ikú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ittai si da ọba lohùn, o si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ati bi oluwa mi ọba ti mbẹ lãye, nitotọ nibikibi ti oluwa mi ọba ba gbe wà, ibakàn ṣe ninu ikú, tabi ninu ìye, nibẹ pẹlu ni iranṣẹ rẹ yio gbe wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ítaì sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Bí OLÚWA tí ń bẹ láàyè, àti bí OLÚWA mi ọba ti ń bẹ láàyè, nítòótọ́ níbikíbi tí OLÚWA mi ọba bá gbé wà, ìbáà ṣe nínú ikú, tàbí nínú ìyè, níbẹ̀ pẹ̀lú ni ìránṣẹ́ rẹ yóò gbé wà.”