2 Samuel 15:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sadoku, alufaa, wà láàrin wọn, àwọn ọmọ Lefi sì wà pẹlu rẹ̀, wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí lọ́wọ́. Wọ́n gbé e kalẹ̀ títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi jáde kúrò ní ìlú. Abiatari, alufaa náà wà láàrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wõ, Sadoku pẹlu ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti o wà lọdọ rẹ̀ si nru apoti-ẹri Ọlọrun: nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na kalẹ; Abiatari si goke, titi gbogbo awọn enia si fi dẹkun ati ma kọja lati ilu wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì wò ó, Sádókù pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run: wọ́n sì gbé àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀; Ábíátarì sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá.