2 Samuel 15:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó tún fi kún un fún Sadoku pé, “Wò ó! Ìwọ ati Abiatari, ẹ pada sí ìlú ní alaafia, mú Ahimaasi, ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun Sadoku alufa pe, Iwọ kọ́ ariran? pada si ilu li alafia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ, Ahimaasi ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí fún Sádókù àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Áhímásì ọmọ rẹ, àti Jónátanì ọmọ Ábíátárì.