2 Samuel 15:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Dafidi gun gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi lọ, láì wọ bàtà, ó ń sọkún bí ó ti ń lọ, ó sì fi aṣọ bo orí rẹ̀ láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, tí wọ́n ń bá a lọ náà fi aṣọ bo orí wọn, wọ́n sì ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si ngoke lọ ni oke Igi ororo, o si nsọkun bi on ti ngoke lọ, o si bò ori rẹ̀, o nlọ laini bata li ẹsẹ: gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀, olukuluku ọkunrin si bò ori rẹ̀, nwọn si ngoke, nwọn si nsọkun bi nwọn ti ngoke lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì ń gòkè lọ ní òkè igi ólífì, o sì ń sunkun bí ó ti ń gòkè lọ, ó sì bo orí rẹ̀, ó ń lọ láìní bàtà ní ẹṣẹ̀: gbogbo ènìyàn tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀, olúkúlùkù ọkùnrin sì bo orí rẹ̀, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sunkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ.