2 Samuel 15:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, Ahitofeli ti darapọ̀ mọ́ ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì, Dafidi gbadura sí OLUWA, ó ní, “Jọ̀wọ́, OLUWA, yí gbogbo ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá fún Absalomu pada sí asán.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikan si sọ fun Dafidi pe, Ahitofeli wà ninu awọn ọlọ̀tẹ̀ Absalomu. Dafidi si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, sọ ìmọ Ahitofeli di asan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnìkan sì sọ fún Dáfídì pé, “Áhítófélì wà nínú àwọn asọ̀tẹ̀ pẹ̀lù Ábúsálómù.” Dáfídì sì wí pé, “OLÚWA, èmi bẹ̀ ọ́, sọ ìmọ̀ Áhítófélì di asán.”