2 Samuel 15:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Dafidi gun òkè náà dé orí, níbi tí wọ́n ti máa ń rúbọ sí Ọlọ́run, Huṣai, ará Ariki, wá pàdé rẹ̀ pẹlu aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya, ó sì ti ku eruku sí orí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, Dafidi de ori oke, nibiti o gbe wolẹ̀ sin Ọlọrun, si wõ, Huṣai ara Arki nì si wá lati pade rẹ̀ ti on ti aṣọ rẹ̀ yiya, ati erupẹ, li ori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe, Dáfídì dé orí òkè, níbi tí ó gbé wólẹ̀ sin Ọlọ́run, sì wò ó, Húsáì ará Áríkà sì wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ yíya, àti erùpẹ̀, lórí rẹ̀.